1 Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?
2 Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,
3 Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn,
4 Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù
5 Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè
6 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín,
7 Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀
8 Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”
9 A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan;
10 Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?
11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?
12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;
13 Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;
14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù
15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;
16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;
17 Ìwọ pààlà etí ayé;
18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa
19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;
20 Bojú wo májẹ̀mú rẹ,
21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú
22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;
23 Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ,