1 Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé;
2 Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé,
3 Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi
4 ‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé
5 Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa,
6 Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa?
7 Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;
8 Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ
9 Ìwọ ń darí ríru omi Òkun;
10 Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ
11 Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ:
12 Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn;
13 Ìwọ ní apá agbára;
14 Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ:
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì,
16 Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,
17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;
18 Nítorí ti Olúwa ni asà wa,
19 Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé,
20 Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi;
21 Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀
22 Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀,
23 Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ
24 Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ
25 Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí òkun,
26 Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘Ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’
27 Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi,
28 Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,
29 Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,
30 “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀
31 Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́
32 nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò;
33 ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
34 Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi,
35 Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra;
36 Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé,
37 A ó fi múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá,
38 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra;
39 Ìwọ ti sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ di òfo;
40 Ìwọ ti wó gbogbo àwọn odi rẹ̀
41 Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ;
42 Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá rẹ̀ sókè;
43 Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà rẹ̀ padà,
44 Ìwọ ti mú ògo rẹ̀ kùnà,
45 Ìwọ ti gé ọjọ́ èwe rẹ̀ kúrú;
46 Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa?
47 Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó
48 Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀?
49 Olúwa, níbo ni ìṣeun ìfẹ́ rẹ àtijọ́ wà,
50 Rántí, Olúwa, bí a ti ń gan àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
51 ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá rẹ gàn, Olúwa,
52 Olùbùkún ní Olúwa títí láé.