1 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
2 Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
3 Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
4 Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
5 Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
6 Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
7 Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
8 “Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
9 Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
14 ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín