1 Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run,
2 Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo,
3 Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn
4 Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn
5 Àwọn òtòṣì àti aláìní
6 Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀,
7 Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀
8 Yóò máa jẹ ọba láti òkun dé òkun
9 Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un
10 Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù
11 Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un
12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní
13 Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní
14 Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá
15 Yóò sì pẹ́ ní ayé!
16 Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀;
17 Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé;
18 Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli,
19 Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé;
20 Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.