1 Gbà mí, Ọlọ́run,
2 Mo ń rì nínú irà jíjìn,
3 Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;
4 Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí
5 Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;
6 Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ nítorí mi,
7 Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,
8 Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;
9 nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run,
10 Nígbà tí mo sọkún
11 nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,
12 Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,
13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni
14 Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀,
15 Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀
16 Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ;
17 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ:
18 Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là;
19 Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá;
20 Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́,
21 Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi,
22 Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn
23 Kí ojú wọn kì í ó ṣókùnkùn, kí wọn má ṣe ríran,
24 Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn;
25 Kí ibùjókòó wọn di ahoro;
26 Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù,
27 Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;
28 Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè
29 Ṣùgbọ́n tálákà àti ẹni-ìkáàánú ni èmí,
30 Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga
31 Eléyìí tẹ́ Olúwa lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ
32 Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀:
33 Olúwa, gbọ́ ti aláìní,
34 Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,
35 nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là
36 àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀,