1 Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi,
2 kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra
3 Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin,
4 Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ,
5 Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú
6 Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè;
7 Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi,
8 Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀,
9 àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́
10 Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn,
11 Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora,
12 Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó!
13 N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu,
14 Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá
15 Mu omi láti inú kànga tìrẹ,
16 Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà
17 Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan,
18 Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún;
19 Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ,
20 Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà,
21 Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò fi ara sin rárá fún Olúwa
22 Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn;
23 Yóò kú ní àìgba ẹ̀kọ́