1 Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi.
2 Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà,
3 Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé
4 Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere
5 Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ
6 Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ
7 Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ
8 Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ
9 Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa,
10 nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya
11 Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa
12 nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí
13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,
14 nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ
15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;
16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;
17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,
18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;
19 Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;
20 nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà,
21 Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́,
22 Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ,
23 Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu,
24 Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù,
25 Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì,
26 Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ,
27 Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ,
28 Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé,
29 Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ,
30 Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí,
31 Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan
32 Nítorí Olúwa kórìíra ènìyàn aláyídáyidà
33 Ègún Olúwa ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú,
34 Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́,
35 Ọlọ́gbọ́n jogún iyì,