1 Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀,
2 Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa,
3 Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàṣán fún ẹ̀yìn rẹ̀,
4 Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní,
5 Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan ni
6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,
7 Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,
8 Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn
9 Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
10 Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀
11 A ó pa ilé ènìyàn búburú run,
12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,
13 Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora;
14 A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,
15 Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́
16 Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi
17 Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè,
18 Òpè jogún ìwà òmùgọ̀
19 Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rere
20 Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀,
21 Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀
22 Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí?
23 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá,
24 Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn
25 Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là
26 Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,
27 Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè,
28 Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba,
29 Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,
30 Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara,
31 Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn
32 Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀,
33 Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóye
34 Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè,
35 Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́n