1 Olúwa kórìíra òsùwọ̀n èké,
2 Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé,
3 Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀,
4 Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú,
5 Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn,
6 Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là,
7 Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun;
8 A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀,
9 Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,
10 Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀;
11 Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga:
12 Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀
13 Olófòófó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀
14 Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú
15 Ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ fún àlejò yóò rí ìyọnu,
16 Obìnrin oníwà rere gba ìyìn
17 Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore
18 Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ
19 Olódodo tòótọ́ rí ìyè
20 Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú
21 Mọ èyí dájú pé, ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà,
22 Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀
23 Ìfẹ́ inú olódodo yóò yọrí sí ohun rere
24 Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i;
25 Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i;
26 Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́
27 Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere
28 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú;
29 Ẹni tí ó ń mú ìdààmú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásán
30 Èso òdodo ni igi ìyè
31 Bí àwọn olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayé