Jó 6

YOR

1 Jobu sì dáhùn ó si wí pé,

2 “Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òsùwọ̀n,

3 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn òkun lọ,

4 Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú,

5 Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,

6 A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,

7 Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò,

8 “Háà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;

9 Àní Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa mí run,

10 Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀,

11 “Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí?

12 Agbára mi ha ṣe agbára òkúta bí?

13 Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi:

14 “Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,

15 Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé

16 Tí ó dúdú nítorí omi dídì,

17 Nígbàkígbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ,

18 Àwọn oníṣòwò yà kúrò ní ọ̀nà wọn,

19 Ẹgbẹ́ oníṣòwò Tema ń wá omi,

20 Wọ́n káàárẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e;

21 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin dàbí wọn;

22 Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá,

23 Tàbí, ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni,

24 “Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́

25 Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó

26 Ẹ̀yin ṣè bí ẹ tún ọ̀rọ̀ mi ṣe

27 Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,

28 “Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.

29 Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀;

30 Àìṣedéédéé ha wà ní ahọ́n mi?

Ler em outra tradução

Comparar lado a lado