1 Nígbà náà ni Elihu dáhùn, ó sì wí pé,
2 “Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,
3 Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò,
4 Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa;
5 “Nítorí pé Jobu wí pé, ‘Aláìlẹ́ṣẹ̀ ni èmi;
6 Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí,
7 Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu,
8 Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó
9 Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn,
10 “Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi,
11 Nítorí pé ó ń sán fún ènìyàn fún gẹ́gẹ́ bi ohun tí a bá ṣe,
12 Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkiwà;
13 Ta ni ó fi ìtọ́jú ayé lé e lọ́wọ́,
14 Bí ó bá gbé ayé rẹ̀ lé kìkì ara rẹ̀
15 gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀,
16 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, bí ìwọ bá ní òye,
17 Ẹni tí ó kórìíra òtítọ́ ha le ṣe olórí bí?
18 O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ‘Ènìyàn búburú ní ìwọ,’
19 mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé
20 Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú,
21 “Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn,
22 Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú,
23 Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan,
24 Òun ó sì fọ́ àwọn alágbára túútúú láìní ìwádìí,
25 nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn,
26 Ó kọlù wọ́n nítorí ìwà búburú wọn
27 nítorí pé wọ́n padà pẹ̀yìndà sí i,
28 kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkún àwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀,
29 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi?
30 kí aláìwà bi Ọlọ́run kí ó má bá à jẹ ọba
31 “Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fún Ọlọ́run pé,
32 Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mi
33 Ǹjẹ́ bí ti inú rẹ̀ ni ki òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà?
34 “Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fún mi,
35 ‘Jobu ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀,
36 Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jobu wò dé òpin,
37 Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;