1 Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé,
2 “Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run?
3 Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmarè pé olódodo ni ìwọ?
4 “Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù
5 Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi,
6 Nítòótọ́ ìwọ béèrè fún ààbò ni ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí,
7 Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu,
8 Bí ó ṣe ti alágbára nì, òun ni ó ní ilẹ̀,
9 Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo,
10 Nítorí náà ni ìdẹ̀kùn ṣe yí ọ káàkiri,
11 Èéṣe tí òkùnkùn fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè ríran.
12 “Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run?
13 Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀?
14 Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ tí ó nípọn jẹ ìbora fún un,
15 Ǹjẹ́ ìwọ fẹ́ rin ipa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọn
16 A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayé láìpé ọjọ́ wọn,
17 Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!
18 Síbẹ̀ ó fi ohun rere kún ilé wọn!
19 Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀,
20 ‘Lóòtítọ́ àwọn ọ̀tá wa ni a ké kúrò,
21 “Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà;
22 Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá,
23 Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró.
24 tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀,
25 nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ,
26 Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè,
27 Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ,
28 Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ;
29 Nígbà tí ipa ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀,
30 Yóò gba ẹni tí kì í ṣe aláìjẹ̀bi là,