1 Ìgbà náà ní Sofari, ará Naama dáhùn, ó sì wí pé,
2 “Nítorí náà ní ìrò inú mi dá mi lóhùn,
3 Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi,
4 “Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́,
5 pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni,
6 Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run,
7 ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀;
8 Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i,
9 Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́,
10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojúrere lọ́dọ̀ tálákà,
11 Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀,
12 “Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀,
13 bí ó tilẹ̀ dá a sì, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
14 ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà,
15 Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde;
16 Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú;
17 Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì,
18 Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì;
19 Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti pẹ̀yìndà si wọ́n;
20 “Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀,
21 Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀;
22 Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a;
23 Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun,
24 Bi o tilẹ̀ sá kúrò lọ́wọ́ ohun ìjà ìrìn;
25 O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára;
26 òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀.
27 Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn,
28 Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ,
29 Èyí ni ìpín ènìyàn búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,