1 Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo,
2 láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn
3 Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirò
4 Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrín àwọn ìgbèkùn
5 “Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi,
6 Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run,
7 Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,
8 ‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.
9 ‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi?
10 Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú,
11 Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ”
12 Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀.
13 Nítorí ó sọ pé:
14 Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,
15 Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í,
16 Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
17 Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná,
18 Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá
19 Àwọn igi tí yóò kù nínú igbó o rẹ̀
20 Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli,
21 Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Israẹli dàbí yanrìn ní Òkun,
23 Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ,
24 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
25 Láìpẹ́, ìbínú mi sí i yín yóò wá sí òpin
26 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba.
27 Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrù wọn kúrò ní èjìká a yín,
28 Wọ́n wọ Aiati,
29 Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé,
30 Gbé ohùn rẹ sókè, ìwọ ọmọbìnrin Galimu!
31 Madmena ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ,
32 Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nobu
33 Wò ó, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
34 Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké,