1 Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani.
2 Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn
3 Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;
4 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani,
5 Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun
6 Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
7 Ní ti gbígbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun.
8 Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu;
9 Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n—
10 Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀
11 Ṣùgbọ́n Olúwa fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́n
12 Àwọn ará Aramu láti ìlà-oòrùn àti Filistini láti ìwọ̀-oòrùn.
13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà
14 Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù
15 àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí,
16 Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà,
17 Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
18 Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná,
19 Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
20 Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun,
21 Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manase