1 Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye,
2 Nígbà náà ni Olúwa dáhùn pé,
3 Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;
4 “Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga,
5 Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn,
6 “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé,
7 Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì?
8 Nítorí ìwọ ti kó Orílẹ̀-èdè púpọ̀,
9 “Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀,
10 Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ
11 Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá,
12 “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú,
13 Olúwa àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé
14 Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,
15 “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,
16 Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú
17 Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́,
18 “Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ,
19 Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘Di alààyè?’
20 Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;