1 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,
2 Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
3 Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
4 Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
5 Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
6 Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
7 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn,
8 Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
9 Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba.”
11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
12 Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀;
13 Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,