1 Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;
2 Tẹ́ etí rẹ sí mi,
3 Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,
4 Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,
5 Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;
6 Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí;
7 Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ,
8 Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́
9 Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;
10 Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi
11 Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo,
12 Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;
13 Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;
14 Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa;
15 Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
16 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;
17 Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa;
18 Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́,
19 Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,
20 Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí
21 Olùbùkún ni Olúwa,
22 Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,
23 Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́!
24 Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le