1 Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?
2 Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:
3 Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ;
4 Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ;
5 Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;
6 Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn;
7 Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;
8 “Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa;
9 Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;
10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá,
11 Má ṣe jìnnà sí mi,
12 Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;
13 Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri,
14 A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,
15 Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,
16 Àwọn ajá yí mi ká;
17 Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi;
18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn
19 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi.
20 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,
21 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún;
22 Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;
23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín!
24 Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra
25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;
26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí
28 nítorí ìjọba ni ti Olúwa.
29 Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn;
30 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín;
31 Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀