1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
2 Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;
3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
6 Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
7 Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa
8 Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
9 Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin,
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
12 Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu;
13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára,
14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀,
15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé
16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn
17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́
18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀
19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀