1 Ẹ yin Olúwa.
2 Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa,
3 Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun;
4 Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀;
5 Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi,
6 Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú,
7 Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá:
8 Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti,
9 Ẹni tí ó rán iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti,
10 Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀,
11 Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu,
12 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,
13 Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé;
14 Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,
15 Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà,
16 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀;
17 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀;
18 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn:
19 Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa,
20 Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa;
21 Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá,