1 Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú
2 nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú,
3 Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́
4 nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún
5 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀,
6 Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà:
7 Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè
8 Ẹni tí ń pète ibi
9 Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
10 Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú
11 Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là;
12 Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,”
13 Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,
14 Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ
15 Má ṣe ba ní ibùba bí ènìyàn búburú
16 nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà méje, yóò tún padà dìde sá á ni,
17 Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú;
18 Àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínú
19 Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi
20 nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú
21 Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi,
22 Nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn,
23 Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n:
24 Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre,”
25 Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi,
26 Ìdáhùn òtítọ́
27 Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ
28 Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí,
29 Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi;
30 Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ,
31 ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo,
32 Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsi
33 oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,
34 òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè