1 “ ‘Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Juda àti egungun àwọn ìjòyè, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jerusalẹmu kúrò nínú ibojì.
2 A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dàbí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀.
3 Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’
4 “Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
5 Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀?
6 Mo ti fetísílẹ̀ dáradára,
7 Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run
8 “ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,
9 Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n,
10 Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn
11 Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi
12 Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn?
13 “ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò,
14 “Èéṣe tí àwa fi jókòó ní ibí yìí?
15 Àwa ń retí àlàáfíà
16 Ìró ìfọn imú ẹṣin àwọn ọlọ̀tẹ̀
17 “Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín,
18 Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi,
19 Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi
20 “Ìkórè ti rékọjá,
21 Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú,
22 Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí?