1 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí,
2 Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi,
3 Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn
4 Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó;
5 A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn,
6 A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta àfonífojì,
7 Wọ́n ń dún ní àárín igbó
8 Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé,
9 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin;
10 Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi,
11 Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú;
12 Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi;
13 Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú;
14 Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru;
15 Ẹ̀rù ńlá bà mí;
16 “Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀;
17 Òru gún mi nínú egungun mi,
18 Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi,
19 Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀,
20 “Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn;
21 Ìwọ padà di ẹni ìkà sí mi;
22 Ìwọ gbé mi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ mú mi fò lọ,
23 Èmi sá à mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú,
24 “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha nawọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubú rẹ̀,
25 Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro?
26 Nígbà tí mo fojú ṣọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé;
27 Ikùn mí n ru kò sì sinmi,
28 Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn;
29 Èmi ti di arákùnrin ìkookò,
30 Àwọ̀ mi di dúdú ní ara mi;
31 Ohun èlò orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀,