1 Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé,
2 “Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀,
3 Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí,
4 Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
5 Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀,
6 kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin,