1 Ẹ fun ìpè ní Sioni,
2 Ọjọ́ òkùnkùn àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀,
3 Iná ń jó níwájú wọ́n;
4 Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin;
5 Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni
6 Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀:
7 Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára;
8 Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò kọlu ẹnìkejì rẹ̀;
9 Wọn yóò sáré síwá sẹ́yìn ní ìlú;
10 Ayé yóò mì níwájú wọn;
11 Olúwa yóò sì bú ramúramù
12 “Ǹjẹ́ nítorí náà nísinsin yìí,” ni Olúwa wí,
13 Ẹ sì fa ọkàn yín ya,
14 Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà,
15 Ẹ fún ìpè ní Sioni,
16 Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ,
17 Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,
18 Nígbà náà ní Olúwa yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀,
19 Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn, yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé:
20 “Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín,
21 Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀;
22 Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó,
23 Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni,
24 Àwọn ilẹ̀ ìpakà yóò kún fún ọkà;
25 “Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín.
26 Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó
27 Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrín Israẹli,
28 “Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́,
29 Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin,
30 Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun
31 A á sọ oòrùn di òkùnkùn,
32 Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè