1 Fetísílẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀;
2 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò,
3 Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa.
4 Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé,
5 Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;
6 Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa,
7 Rántí ìgbà láéláé;
8 Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn,
9 Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,
10 Ní aginjù ni ó ti rí i,
11 Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń
12 Olúwa ṣamọ̀nà;
13 Ó mú gun ibi gíga ayé
14 Pẹ̀lú u wàràǹkàṣì àti wàrà àgùntàn
15 Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá;
16 Wọ́n sì fi òrìṣà mú un jowú,
17 Wọ́n rú ẹbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,
18 Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ;
19 Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,
20 Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn,
21 Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,
22 Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú mi,
23 “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lórí
24 Èmi yóò mú wọn gbẹ,
25 Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù,
26 Mo ní èmi yóò tú wọn ká
27 nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá,
28 Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀,
29 Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn
30 Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún (1,000),
31 Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa,
32 Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomu
33 Ọtí wáìnì wọn ìwọ ti dragoni ni,
34 “Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́
35 Ti èmi ni láti gbẹ̀san. Èmi yóò san án fún wọn
36 Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀
37 Yóò wí pé, “Òrìṣà wọn dà báyìí,
38 ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọn
39 “Wò ó báyìí pé, Èmi fúnra à mi, Èmi ni!
40 Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé,
41 nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán mi
42 Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,
43 Ẹ yọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀
44 Mose sì wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ní etí àwọn ènìyàn náà, òun, àti Hosea ọmọ Nuni.
45 Nígbà tí Mose parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Israẹli.
46 Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ láàrín yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́rọ̀ àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.
47 Wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jordani lọ láti gbà.”
48 Ní ọjọ́ kan náà, Olúwa sọ fún Mose pé,
49 “Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn.
50 Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kùú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Aaroni ti kú ní orí òkè Hori tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀.
51 Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrín àwọn ọmọ Israẹli ní ibi omi Meriba Kadeṣi ní aginjù Sini àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrín àwọn ọmọ Israẹli.
52 Nítorí náà, ìwọ yóò rí ilẹ̀ náà ní ọ̀kánkán, o kì yóò wọ inú rẹ̀ ilẹ̀ ti mo ti fi fún àwọn ọmọ Israẹli.”