1 Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni
2 Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó
3 Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú,
4 Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe
5 Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi
6 Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan
7 Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn
8 Olúwa Olódùmarè ti búra fúnra rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé:
9 Bí ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú.
10 Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.”
11 Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà,
12 Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí?
13 Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari,
14 Nítorí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí pé,