1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá: wí pé:
2 “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
3 Nítorí ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí
4 Idà yóò wá sórí Ejibiti
5 Kuṣi àti Puti, Libia, Ludi àti gbogbo Arabia, Kubu àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó mulẹ̀ yóò ṣubú nípa idà pẹ̀lú Ejibiti.
6 “ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí:
7 Wọn yóò sì wà
8 Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
9 “ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kuṣi tí ó wà nínú àlàáfíà. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Ejibiti. Kíyèsi i, ó dé.
10 “ ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
11 Òun àti àwọn ológun rẹ̀
12 Èmi yóò mú kí àwọn odò Naili gbẹ,
13 “ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
14 Èmi yóò sì mú kí Paturosi di ahoro,
15 Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pelusiumu
16 Èmi yóò ti iná bọ Ejibiti
17 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Heliopolisi àti Bubasiti
18 Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tafanesi
19 Nítorí náà, Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Ejibiti,
20 Ní ọjọ́ keje oṣù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá,
21 “Ọmọ ènìyàn, Èmi ti ṣẹ́ apá Farao ọba Ejibiti. A kò ì tí ì di apá náà papọ̀ láti mu kí ó san, a kò sì ti di i si àárín igi pẹlẹbẹ kí o lè ni agbára tó láti di idà mú.
22 Nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí Farao ọba Ejibiti. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀.
23 Èmi yóò sì fọ́n àwọn ènìyàn Ejibiti ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká gbogbo ilẹ̀.
24 Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Farao, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a sá ní àṣápa.
25 Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli lé, ṣùgbọ́n apá Farao yóò sì rọ. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ ọba Babeli yóò sì fi idà náà kọlu Ejibiti.
26 Èmi yóò fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí gbogbo ilẹ̀. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”