1 Àwọn ọmọ Lefi:
2 Àwọn ọmọ Kohati:
3 Àwọn ọmọ Amramu:
4 Eleasari jẹ́ baba Finehasi,
5 Abiṣua baba Bukki,
6 Ussi baba Serahiah,
7 Meraioti baba Amariah,
8 Ahitubu baba Sadoku,
9 Ahimasi baba Asariah,
10 Johanani baba Asariah.
11 Asariah baba Amariah
12 Ahitubu baba Sadoku.
13 Ṣallumu baba Hilkiah,
14 Asariah baba Seraiah,
15 A kó Josadaki lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Juda àti Jerusalẹmu kúrò ní ìlú nípasẹ̀ Nebukadnessari.
16 Àwọn ọmọ Lefi:
17 Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni:
18 Àwọn ọmọ Kohati:
19 Àwọn ọmọ Merari:
20 Ti Gerṣoni:
21 Joah ọmọkùnrin rẹ̀,
22 Àwọn ìran ọmọ Kohati:
23 Elkana ọmọkùnrin rẹ̀,
24 Tahati ọmọkùnrin rẹ̀, Urieli ọmọkùnrin rẹ̀,
25 Àwọn ìran ọmọ Elkana:
26 Elkana ọmọ rẹ̀, Sofai ọmọ rẹ̀
27 Eliabu ọmọ rẹ̀,
28 Àwọn ọmọ Samuẹli:
29 Àwọn ìran ọmọ Merari:
30 Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀
31 Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀.
32 Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.
33 Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn.
34 ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu,
35 ọmọ Sufu, ọmọ Elkana,
36 ọmọ Elkana, ọmọ Joẹli,
37 ọmọ Tahati, ọmọ Asiri,
38 ọmọ Isari, ọmọ Kohati,
39 Hemani sì darapọ̀ mọ́ Asafu, ẹni tí o sìn ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀:
40 ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah,
41 ọmọ Etini,
42 ọmọ Etani, ọmọ Simma,
43 ọmọ Jahati,
44 láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Merari wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀:
45 ọmọ Haṣabiah,
46 ọmọ Amisi, ọmọ Bani,
47 ọmọ Mahili,
48 Àwọn Lefi ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yòókù ti àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run.
49 Ṣùgbọ́n Aaroni àti àwọn ìran ọmọ rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ṣe ní Ibi Mímọ́ Jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Israẹli, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pàṣẹ.
50 Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Aaroni:
51 Bukki ọmọ rẹ̀,
52 Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀,
53 Sadoku ọmọ rẹ̀
54 Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbègbè wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Aaroni lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kohati, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ tiwọn).
55 A fún wọn ní Hebroni ní Juda pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.
56 Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún Kalebu ọmọ Jefunne.
57 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Aaroni ni a fún ní Hebroni (ìlú ti ààbò), àti Libina, Jattiri, Eṣitemoa,
58 Hileni, Debiri,
59 Aṣani, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.
60 Àti láti inú ẹ̀yà Benjamini, a fún wọn ní Gibeoni, Geba, Alemeti àti Anatoti lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
61 Ìyókù àwọn ìran ọmọ Kohati ní a pín ìlú mẹ́wàá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase.
62 Àwọn ìran ọmọ Gerṣoni, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Isakari, Aṣeri àti Naftali, àti láti apá ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Baṣani.
63 Sebuluni àwọn ìran ọmọ Merari, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.
64 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ará Lefi ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
65 Láti ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.
66 Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn.
67 Ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, a fún wọn ní Ṣekemu (ìlú ńlá ti ààbò), àti Geseri
68 Jokimeamu, Beti-Horoni.
69 Aijaloni àti Gati-Rimoni lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
70 Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Manase àwọn ọmọ Israẹli fún Aneri àti Bileamu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kohati.
71 Àwọn ará Gerṣoni gbà nǹkan wọ̀nyí.
72 Láti ẹ̀yà Isakari wọ́n gba Kedeṣi, Daberati
73 Ramoti àti Anenu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
74 Láti ẹ̀yà Aṣeri wọ́n gba Maṣali, Abdoni,
75 Hukoki àti Rehobu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
76 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
77 Àwọn ará Merari (ìyókù àwọn ará Lefi) gbà nǹkan wọ̀nyí.
78 Láti ẹ̀yà Reubeni rékọjá Jordani ìlà-oòrùn Jeriko wọ́n gba Beseri nínú aginjù Jahisa,
79 Kedemoti àti Mefaati, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
80 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu,
81 Heṣboni àti Jaseri lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.