1 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run.
2 Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ Olúwa.
3 Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan.
4 Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Lefi láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.
5 Asafu ni olóyè, àtẹ̀lé rẹ ni Sekariah, Jehieli, Ṣemiramotu, Asieli, Mattitiah, Eliabu, Benaiah, Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn ni yóò lu ohun èlò orin olókùn àti dùùrù haapu. Asafu ni yóò lu símbálì kíkan.
6 Àti Benaiah àti Jahasieli àwọn àlùfáà ni yóò fọn ìpè nígbà gbogbo níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú ti Ọlọ́run.
7 Ní ọjọ́ náà Dafidi kọ́kọ́ fi lé Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dafidi ti ọpẹ́ sí Olúwa.
8 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ẹ pe orúkọ rẹ̀,
9 Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn, sí i,
10 Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́;
11 Ẹ wá Olúwa àti agbára rẹ̀;
12 Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe,
13 A! ẹ̀yin ìran ọmọ Israẹli ìránṣẹ́ rẹ̀,
14 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa;
15 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,
16 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,
17 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu,
18 “Sí ọ, ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kenaani.
19 Nígbà tí wọn kéré ní iye,
20 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè
21 Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú;
22 “Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi;
23 Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé;
24 Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
25 Nítorí títóbi ni Olúwa òun sì ni ìyìn yẹ jùlọ;
26 Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà,
27 Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀;
28 Fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè,
29 Fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀;
30 Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé!
31 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn;
32 Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀;
33 Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin,
34 Fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára;
35 Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run olùgbàlà a wa;
36 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli,
37 Dafidi fi Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa láti jíṣẹ́ níbẹ̀ déédé, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà.
38 Ó fi Obedi-Edomu àti méjìdínláàádọ́rin ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Obedi-Edomu mọ Jedutuni, àti Hosa pẹ̀lú jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà.
39 Dafidi fi Sadoku àlùfáà àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níwájú Àgọ́ Olúwa ní ibi gíga ní Gibeoni.
40 Láti gbé pẹpẹ ẹbọ sísun déédé, àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí a kọ sínú òfin Olúwa, tí ó ti fún Israẹli.
41 Pẹ̀lú wọn ni Hemani àti Jedutuni àti ìyókù tí a mú àti yàn nípasẹ̀ orúkọ láti fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé
42 Hemani àti Jedutuni ni wọ́n dúró fún fífọn ìpè àti Kimbali àti fún lílo ohun èlò yòókù fún orin Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Jedutuni wà ní ipò dídúró ní ẹnu-ọ̀nà.
43 Nígbà náà gbogbo àwọn ènìyàn kúrò, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀: Dafidi yípadà láti súre fún ìdílé rẹ̀.